O. Daf 48

48
OLUWA Tóbi
1ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀.
2Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla.
3A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀.
4Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ.
5Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ.
6Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi.
7Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi.
8Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai.
9Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ.
10Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo.
11Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ.
12Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀.
13Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin.
14Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 48: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa