ỌLỌRUN li àbo wa ati agbara, lọwọlọwọ iranlọwọ ni igba ipọnju. Nitorina li awa kì yio bẹ̀ru, bi a tilẹ ṣi aiye ni idi, ti a si ṣi awọn oke nla nipò lọ si inu okun: Bi omi rẹ̀ tilẹ nho ti o si nru, bi awọn òke nla tilẹ nmì nipa ọwọ bibì rẹ̀. Odò nla kan wà, ṣiṣan eyiti yio mu inu ilu Ọlọrun dùn, ibi mimọ́ agọ wọnni ti Ọga-ogo. Ọlọrun mbẹ li arin rẹ̀; a kì yio ṣi i ni idi: Ọlọrun yio ràn a lọwọ ni kutukutu owurọ. Awọn keferi nbinu, awọn ilẹ ọba ṣidi: o fọhun rẹ̀, aiye yọ́. Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa. Ẹ wá wò awọn iṣẹ Oluwa, iru ahoro ti o ṣe ni aiye. O mu ọ̀tẹ tan de opin aiye; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ meji; o si fi kẹkẹ́ ogun jona. Ẹ duro jẹ, ki ẹ si mọ̀ pe emi li Ọlọrun, a o gbé mi ga ninu awọn keferi, a o gbé mi ga li aiye. Oluwa awọn ọmọ-ogun wà pẹlu wa; Ọlọrun Jakobu li àbo wa.
Kà O. Daf 46
Feti si O. Daf 46
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 46:1-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò