IBUKÚN ni fun ẹniti nrò ti awọn alaini, Oluwa yio gbà a ni ìgbà ipọnju. Oluwa yio pa a mọ́, yio si mu u wà lãye; a o si bukún fun u lori ilẹ: iwọ kì yio si fi i le ifẹ awọn ọta rẹ̀ lọwọ. Oluwa yio gbà a ni iyanju lori ẹní àrun: iwọ o tẹ ẹní rẹ̀ gbogbo ni ibulẹ arun rẹ̀. Emi wipe, Oluwa ṣãnu fun mi: mu ọkàn mi lara da; nitori ti mo ti ṣẹ̀ si ọ. Awọn ọta mi nsọ ibi si mi pe, nigbawo ni on o kú, ti orukọ rẹ̀ yio si run? Bi o ba si wá wò mi, on a ma sọ̀rọ ẹ̀tan: aiya rẹ̀ kó ẹ̀ṣẹ jọ si ara rẹ̀; nigbati o ba jade lọ, a ma wi i. Gbogbo awọn ti o korira mi jumọ nsọ̀rọ kẹlẹ́ si mi: emi ni nwọn ngbìmọ ibi si. Pe, ohun buburu li o dì mọ ọ ṣinṣin: ati ibiti o dubulẹ si, kì yio dide mọ. Nitõtọ ọrẹ-iyọrẹ ara mi, ẹniti mo gbẹkẹle, ẹniti njẹ ninu onjẹ mi, o gbe gigisẹ rẹ̀ si mi. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, ṣãnu fun mi, ki o si gbé mi dide, ki emi ki o le san a fun wọn. Nipa eyi ni mo mọ̀ pe iwọ ṣe oju-rere si mi, nitoriti awọn ọta mi kò yọ̀ mi. Bi o ṣe ti emi ni, iwọ dì mi mu ninu ìwatitọ mi, iwọ si gbé mi kalẹ niwaju rẹ titi lai. Olubukún ni Oluwa, Ọlọrun Israeli, lailai titi lai. Amin, Amin.
Kà O. Daf 41
Feti si O. Daf 41
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 41:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò