O. Daf 35:1-16

O. Daf 35:1-16 YBCV

OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà. Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi. Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ. Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi. Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn. Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn. Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi. Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si. Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀. Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun? Awọn ẹlẹri eke dide; nwọn mbi mi li ohun ti emi kò mọ̀. Nwọn fi buburu san ore fun mi, lati sọ ọkàn mi di ofo. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, nigbati ara wọn kò dá, aṣọ àwẹ li aṣọ mi: mo fi àwẹ rẹ̀ ọkàn mi silẹ; adura mi si pada si mi li aiya. Emi ṣe ara mi bi ẹnipe ọrẹ tabi arakunrin mi tilẹ ni: emi fi ibinujẹ tẹriba, bi ẹniti nṣọ̀fọ iya rẹ̀. Ṣugbọn ninu ipọnju mi nwọn yọ̀, nwọn si kó ara wọn jọ: awọn enia-kenia kó ara wọn jọ si mi, emi kò si mọ̀; nwọn fa mi ya, nwọn kò si dakẹ. Pẹlu awọn àgabagebe ti iṣe ẹlẹya li apejẹ, nwọn npa ehin wọn si mi.