OLUWA gbogun tì awọn ti o gbogun tì mi: fi ìja fun awọn ti mba mi jà. Di asà on apata mu, ki o si dide fun iranlọwọ mi. Fa ọ̀kọ yọ pẹlu, ki o si dèna awọn ti nṣe inunibini si mi: wi fun ọkàn mi pe, emi ni igbala rẹ. Ki nwọn ki o dãmu, ki a si tì awọn ti nwá ọkàn mi loju: ki a si mu wọn pada, ki a si dãmu awọn ti ngbiro ipalara mi. Ki nwọn ki o dabi iyangbo niwaju afẹfẹ: ki angeli Oluwa ki o ma le wọn. Ki ọ̀na wọn ki o ṣokunkun ki o si ma yọ́; ki angeli Oluwa ki o si ma lepa wọn. Nitori pe, li ainidi ni nwọn dẹ àwọn wọn silẹ fun mi, nwọn wà iho silẹ fun ọkàn mi li ainidi. Ki iparun ki o wá si ori rẹ̀ li ojiji; àwọn rẹ̀ ti o dẹ, ki o mu on tikararẹ̀: iparun na ni ki o ṣubu si. Ọkàn mi yio si ma yọ̀ niti Oluwa: yio si ma yọ̀ ninu igbala rẹ̀. Gbogbo egungun mi ni yio wipe, Oluwa, tali o dabi iwọ, ti ngbà talaka lọwọ awọn ti o lagbara jù u lọ, ani talaka ati alaini lọwọ ẹniti nfi ṣe ikogun?
Kà O. Daf 35
Feti si O. Daf 35
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 35:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò