EMI o ma fi ibukún fun Oluwa nigbagbogbo: Iyìn rẹ̀ yio ma wà li ẹnu mi titi lai. Ọkàn mi yio ma ṣogo rẹ̀ niti Oluwa: awọn onirẹlẹ yio gbọ́, inu wọn yio si ma dùn. Gbé Oluwa ga pẹlu mi, ki a si jumọ gbé orukọ rẹ̀ leke. Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn. Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e. Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara.
Kà O. Daf 34
Feti si O. Daf 34
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 34:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò