O. Daf 33:1-22

O. Daf 33:1-22 YBCV

ẸMA yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo: nitoriti iyìn yẹ fun ẹni-diduro-ṣinṣin. Ẹ ma fi duru yìn Oluwa: ẹ ma fi ohun-elo olokùn mẹwa kọrin si i. Ẹ kọ orin titun si i: ẹ ma fi ọgbọngbọn lù ohun ọnà orin pẹlu ariwo. Nitori ti ọ̀rọ Oluwa tọ́: ati gbogbo iṣẹ rẹ̀ li a nṣe ninu otitọ. O fẹ otitọ ati idajọ: ilẹ aiye kún fun ãnu Oluwa. Nipa ọ̀rọ Oluwa li a da awọn ọrun, ati gbogbo ogun wọn nipa ẽmí ẹnu rẹ̀. O gbá awọn omi okun jọ bi ẹnipe òkiti kan: o tò ibu jọ ni ile iṣura. Ki gbogbo aiye ki o bẹ̀ru Oluwa: ki gbogbo araiye ki o ma wà ninu ẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o sọ̀rọ, o si ti ṣẹ; o paṣẹ, o si duro ṣinṣin. Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki. Imọ Oluwa duro lailai, ìro inu rẹ̀ lati irandiran. Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀. Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia. Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn. Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ. Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ. Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀; Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa. Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́. Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa