O. Daf 16

16
Mo Sá di OLUWA
1ỌLỌRUN, pa mi mọ́: nitori iwọ ni mo gbẹkẹ mi le.
2Ọkàn mi, iwọ ti wi fun Oluwa pe, Iwọ li Oluwa mi: emi kò ni ire kan lẹhin rẹ.
3Si awọn enia mimọ́ ti o wà li aiye, ani si awọn ọlọla, lara ẹniti didùn inu mi gbogbo gbe wà.
4Ibinujẹ awọn ti nsare tọ̀ ọlọrun miran lẹhin yio pọ̀: ẹbọ ohun mimu ẹ̀jẹ wọn li emi kì yio ta silẹ, bẹ̃li emi kì yio da orukọ wọn li ẹnu mi.
5Oluwa ni ipin ini mi, ati ti ago mi: iwọ li o mu ìla mi duro.
6Okùn tita bọ́ sọdọ mi ni ibi daradara; lõtọ, emi ni ogún rere.
7Emi o fi ibukún fun Oluwa, ẹniti o ti nfun mi ni ìmọ; ọkàn mi pẹlu nkọ́ mi ni wakati oru.
8Emi ti gbé Oluwa kà iwaju mi nigbagbogbo; nitori o wà li ọwọ ọtún mi, a kì yio ṣi mi ni ipò.
9Nitorina ni inu mi ṣe dùn, ti ogo mi si nyọ̀; ara mi pẹlu yio simi ni ireti.
10Nitori iwọ kì yio fi ọkàn mi silẹ ni ipò-okú; bẹ̃ni iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ki o ri idibajẹ.
11Iwọ o fi ipa ọ̀na ìye hàn mi; ni iwaju rẹ li ẹkún ayọ̀ wà: li ọwọ ọtún rẹ ni didùn-inu wà lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 16: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀