OLUWA, tani yio ma ṣe atipo ninu agọ rẹ? tani yio ma gbe inu òke mimọ́ rẹ? Ẹniti o nrìn dede, ti nṣiṣẹ ododo, ti o si nsọ otitọ inu rẹ̀. Ẹniti kò fi ahọn rẹ̀ sọ̀rọ ẹni lẹhin, ti kò si ṣe ibi si ẹnikeji rẹ̀, ti kò si gbà ọ̀rọ ẹ̀gan si ẹnikeji rẹ̀. Li oju ẹniti enia-kenia di gigàn; ṣugbọn a ma bu ọla fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa. Ẹniti o bura si ibi ara rẹ̀, ti kò si yipada. Ẹniti kò fi owo rẹ̀ gbà èle, ti kò si gbà owo ẹ̀bẹ si alaiṣẹ. Ẹniti o ba ṣe nkan wọnyi kì yio yẹsẹ lailai.
Kà O. Daf 15
Feti si O. Daf 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 15:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò