Ẹ fi iyìn fun Oluwa. Ẹ kọ orin titun si Oluwa, ati iyìn rẹ̀ ninu ijọ awọn enia-mimọ́. Jẹ ki Israeli ki o yọ̀ si ẹniti o dá a; jẹ ki awọn ọmọ Sioni ki o kún fun ayọ̀ si Ọba wọn. Jẹ ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ̀ ninu ijó: jẹ ki nwọn ki o fi ìlu ati dùru kọrin iyìn si i. Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà. Jẹ ki awọn enia mimọ́ ki o kún fun ayọ̀ ninu ogo; ki nwọn ki o mã kọrin kikan lori ẹni wọn. Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn; Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia. Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn; Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Kà O. Daf 149
Feti si O. Daf 149
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 149:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò