OLUWA, emi kigbe pè ọ: yara si ọdọ mi; fi eti si ohùn mi, nigbati mo ba nkepè ọ. Jẹ ki adura mi ki o wá si iwaju rẹ bi ẹbọ turari; ati igbé ọwọ mi soke bi ẹbọ aṣãlẹ. Oluwa, fi ẹṣọ́ siwaju ẹnu mi; pa ilẹkun ète mi mọ́. Máṣe fà aiya mi si ohun ibi kan, lati ma ba awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ ṣiṣẹ buburu; má si jẹ ki emi ki o jẹ ninu ohun didùn wọn. Jẹ ki olododo ki o lù mi; iṣeun ni yio jasi: jẹ ki o si ba mi wi; ororo daradara ni yio jasi, ti kì yio fọ́ mi lori: sibẹ adura mi yio sa wà nitori jamba wọn. Nigbati a ba bì awọn onidajọ wọn ṣubu ni ibi okuta, nwọn o gbọ́ ọ̀rọ mi, nitori ti o dùn. Egungun wa tàn kalẹ li ẹnu isà-òkú, ẹniti o la aporo sori ilẹ. Ṣugbọn oju mi mbẹ lara rẹ; Ọlọrun Oluwa, lọdọ rẹ ni igbẹkẹle mi wà; máṣe tú ọkàn mi dà silẹ. Pa mi mọ́ kuro ninu okùn ti nwọn dẹ silẹ fun mi, ati ikẹkùn awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Jẹ ki awọn enia buburu ki o bọ́ sinu àwọn ara wọn, nigbati emi ba kọja lọ.
Kà O. Daf 141
Feti si O. Daf 141
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 141:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò