OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi. Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére. Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ. Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata. Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi. Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ.
Kà O. Daf 139
Feti si O. Daf 139
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 139:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò