NIGBATI Oluwa mu ikólọ Sioni pada, awa dabi ẹniti nla alá. Nigbana li ẹnu wa kún fun ẹrin, ati ahọn wa kọ orin: nigbana ni nwọn wi ninu awọn keferi pe, Oluwa ṣe ohun nla fun wọn. Oluwa ṣe ohun nla fun wa: nitorina awa nyọ̀. Oluwa mu ikólọ wa pada, bi iṣan-omi ni gusu. Awọn ti nfi omije fún irugbin yio fi ayọ ka. Ẹniti nfi ẹkun rìn lọ, ti o si gbé irugbin lọwọ, lõtọ, yio fi ayọ̀ pada wá, yio si rù iti rẹ̀.
Kà O. Daf 126
Feti si O. Daf 126
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 126:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò