Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo.
Kà O. Daf 119
Feti si O. Daf 119
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 119:14-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò