O. Daf 104

104
Yíyin Ẹlẹ́dàá
1FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ.
2Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita:
3Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ:
4Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀.
5Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai.
6Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla.
7Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ.
8Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn.
9Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ.
10Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke.
11Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn;
12Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi.
13O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun.
14O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá;
15Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le.
16Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn.
17Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.
18Awọn òke giga li àbo fun awọn ewurẹ igbẹ: ati awọn apata fun awọn ehoro.
19O da oṣupa fun akokò: õrùn mọ̀ akokò ìwọ rẹ̀.
20Iwọ ṣe òkunkun, o si di oru: ninu eyiti gbogbo ẹranko igbo nrìn kiri.
21Awọn ẹgbọrọ kiniun ndún si ohun ọdẹ wọn, nwọn si nwá onjẹ wọn lọwọ Ọlọrun.
22Õrùn là, nwọn kó ara wọn jọ, nwọn dubulẹ ninu iho wọn.
23Enia jade lọ si iṣẹ rẹ̀ ati si lãla rẹ̀ titi di aṣalẹ.
24Oluwa, iṣẹ rẹ ti pọ̀ to! ninu ọgbọ́n ni iwọ ṣe gbogbo wọn: aiye kún fun ẹ̀da rẹ.
25Bẹ̃li okun yi ti o tobi, ti o si ni ibò, nibẹ ni ohun ainiye nrakò, ati ẹran kekere ati nla.
26Nibẹ li ọkọ̀ nrìn: nibẹ ni lefiatani nì wà, ti iwọ da lati ma ṣe ariya ninu rẹ̀.
27Gbogbo wọnyi li o duro tì ọ; ki iwọ ki o le ma fun wọn li onjẹ wọn li akokò wọn.
28Eyi ti iwọ fi fun wọn ni nwọn nkó: iwọ ṣí ọwọ rẹ, a si fi ohun rere tẹ́ wọn lọrùn.
29Iwọ pa oju rẹ mọ́, ara kò rọ̀ wọn: iwọ gbà ẹmi wọn, nwọn kú, nwọn si pada si erupẹ wọn.
30Iwọ rán ẹmi rẹ jade, a si da wọn: iwọ si sọ oju ilẹ di ọtun.
31Ogo Oluwa yio wà lailai: Oluwa yio yọ̀ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀.
32O bojuwo aiye, o si warìrì: o fi ọwọ kàn òke, nwọn si ru ẹ̃fin.
33Emi o ma kọrin si Oluwa nigbati mo wà lãye: emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun mi ni igba aiye mi.
34Jẹ ki iṣaro mi ki o mu inu rẹ̀ dùn: emi o mã yọ̀ ninu Oluwa.
35Jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ ki o run kuro li aiye, ki awọn enia buburu ki o má si mọ. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 104: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa