O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli. Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu. On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa. Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.
Kà O. Daf 103
Feti si O. Daf 103
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 103:7-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò