O. Daf 103:1-22

O. Daf 103:1-22 YBCV

FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀: Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ, Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade: Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì. Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara. O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli. Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu. On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa. Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa. Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ. Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́. Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ: Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn. Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo; Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀. Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀. Ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ̀ ni ibi gbogbo ijọba rẹ̀: fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.

Verse Images for O. Daf 103:1-22

O. Daf 103:1-22 - FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́.
Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀:
Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ,
Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade:
Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì.
Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara.
O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli.
Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu.
On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai.
On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa.
Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.
Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa.
Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.
Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa.
Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ.
Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́.
Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ:
Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn.
Oluwa ti pèse itẹ́ rẹ̀ ninu ọrun; ijọba rẹ̀ li o si bori ohun gbogbo;
Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀.
Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀ gbogbo; ẹnyin iranṣẹ rẹ̀, ti nṣe ifẹ rẹ̀.
Ẹ fi ibukún fun Oluwa, gbogbo iṣẹ rẹ̀ ni ibi gbogbo ijọba rẹ̀: fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa