Dide, Oluwa; Ọlọrun, gbé ọwọ rẹ soke: máṣe gbagbe olupọnju. Ẽṣe ti enia buburu fi ngàn Ọlọrun? o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Iwọ kì yio bère. Iwọ ti ri i; nitori iwọ nwò ìwa-ìka ati iwọsi, lati fi ọ̀ran na le ọwọ rẹ; talaka fi ara rẹ̀ le ọ lọwọ; iwọ li oluranlọwọ alaini-baba. Ṣẹ́ apa enia buburu, ati ti ọkunrin ibi nì: iwọ wá ìwa-buburu rẹ̀ ri, titi iwọ kì yio fi ri i mọ́. Oluwa li ọba lai ati lailai: awọn keferi run kuro ni ilẹ rẹ̀. Oluwa, iwọ ti gbọ́ ifẹ onirẹlẹ: iwọ o mu ọkàn wọn duro, iwọ o dẹ eti rẹ si i. Lati ṣe idajọ alaini-baba ati ẹni-inilara, ki ọkunrin aiye ki o máṣe daiya-fo-ni mọ́.
Kà O. Daf 10
Feti si O. Daf 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 10:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò