Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara. Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona? Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀. Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run.
Kà Owe 6
Feti si Owe 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 6:25-32
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò