Owe 5

5
Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè
1ỌMỌ mi, fiyesi ọgbọ́n mi, ki o si dẹti rẹ si oye mi.
2Lati ma pa ironu mọ́, ati ki ète rẹ ki o le ma pa ìmọ mọ́.
3Nitori ti ète awọn ajeji obinrin a ma kán bi oyin, ẹnu rẹ̀ si kunna ju ororo lọ:
4Ṣugbọn igbẹhin rẹ̀ koro bi idápa, o si mú bi idà olojumeji.
5Ẹsẹ rẹ̀ nsọkalẹ lọ sinu ikú, ìrin-ẹsẹ rẹ̀ de ipo-okú.
6Ki iwọ má ba ja ipa-ọ̀na ìye, ipa-ọ̀na rẹ̀ a ma yi sihin yi sọhun, on kò si mọ̀.
7Njẹ gbọ́ temi nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ki ẹnyin ki o máṣe yà kuro li ọ̀rọ ẹnu mi.
8Takete kuro lọdọ rẹ̀, má si ṣe sunmọ eti ilẹkun ile rẹ̀:
9Ki iwọ ki o má ba fi ọlá rẹ fun ẹlomiran, ati ọdun rẹ fun ẹni-ìka;
10Ki a má ba fi ọrọ̀ rẹ fun ajeji enia; ki ère-iṣẹ ọwọ rẹ ki o má ba wà ni ile alejo.
11Iwọ a si ma kãnu ni ikẹhin rẹ̀, nigbati ẹran-ara ati ara rẹ ba parun.
12Iwọ a si wipe, emi ha ti korira ẹkọ́ to, ti aiya mi si gàn ìbawi:
13Ti emi kò gbà ohùn awọn olukọ́ mi gbọ́, tabi ki emi dẹti mi silẹ si awọn ti nkọ́ mi.
14Emi fẹrẹ wà ninu ibi patapata larin awujọ, ati ni ijọ.
15Mu omi lati inu kudu rẹ, ati omi ti nṣàn lati inu kanga rẹ.
16Jẹ ki isun rẹ ki o ṣàn kakiri, ati awọn odò omi ni ita.
17Ki nwọn ki o jẹ kiki tirẹ, ki o má ṣe ti awọn ajeji pẹlu rẹ.
18Jẹ ki orisun rẹ ki o ni ibukun: ki iwọ ki o si ma yọ̀ tiwọ ti aya ìgba-èwe rẹ.
19Bi abo agbọnrin daradara ati abo igalà, jẹ ki ọmu rẹ̀ ki o ma fi ayọ̀ kún ọ nigbagbogbo; ki o si ma yọ̀ gidigidi ninu ifẹ rẹ̀ nigbakugba.
20Ọmọ mi, ẽṣe ti iwọ o fi ma yọ̀ ninu ifẹ ajeji obinrin, ti iwọ o fi gbá aiya ajeji obinrin mọra?
21Nitoripe ọ̀na enia mbẹ niwaju Oluwa, o si nṣiwọ̀n irin wọn gbogbo.
22Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.
23Yio kú li aigbà ẹkọ́, ati ninu ọ̀pọlọpọ were rẹ̀ yio si ma ṣina kiri.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 5: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀