Owe 4:1-27

Owe 4:1-27 YBCV

ENYIN ọmọ, ẹ gbọ́ ẹkọ́ baba, ki ẹ si fiyesi ati mọ̀ oye. Nitori ti mo fun nyin li ẹkọ rere, ẹ máṣe kọ̀ ofin mi silẹ. Nitoripe ọmọ baba mi li emi iṣe, ẹni-ikẹ́ ati olufẹ li oju iya mi. On si kọ́ mi pẹlu, o si wi fun mi pe, jẹ ki aiya rẹ ki o gbà ọ̀rọ mi duro: pa ofin mi mọ́ ki iwọ ki o si yè. Ni ọgbọ́n, ni oye: máṣe gbagbe; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fà sẹhin kuro li ọ̀rọ ẹnu mi. Máṣe kọ̀ ọ silẹ, yio si mu ọ tọ́: fẹ ẹ, yio si pa ọ mọ́. Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye. Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra. On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ. Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ. Emi ti kọ́ ọ li ọ̀na ọgbọ́n; emi ti mu ọ tọ̀ ipa-ọ̀na titọ. Nigbati iwọ nrìn, ọ̀na rẹ kì yio há fun àye; nigbati iwọ nsare, iwọ kì yio fi ẹsẹ kọ. Di ẹkọ́ mu ṣinṣin, máṣe jẹ ki o lọ; pa a mọ́, nitori on li ẹmi rẹ. Máṣe bọ si ipa-ọ̀na enia buburu, má si ṣe rìn li ọ̀na awọn enia ibi. Yẹ̀ ẹ silẹ, máṣe kọja ninu rẹ̀, yẹ̀ kuro nibẹ, si ma ba tirẹ lọ. Nitoriti nwọn kì isùn bikoṣepe nwọn hùwa buburu; orun wọn a si dá, bikoṣepe nwọn ba mu enia ṣubu. Nitori ti nwọn njẹ onjẹ ìwa-ika, nwọn si nmu ọti-waini ìwa-agbara. Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan. Ọna awọn enia buburu dabi òkunkun: nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn ndugbolu. Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye. Mu arekereke kuro lọdọ rẹ, ati ète ẹ̀tan jina rére kuro lọdọ rẹ. Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ. Máṣe yà si apa ọtun tabi si apa òsi, ṣi ẹsẹ rẹ kuro ninu ibi.