Owe 22:1-29

Owe 22:1-29 YBCV

ORUKỌ rere sàn ni yiyàn jù ọrọ̀ pupọ lọ, ati ojurere ifẹ jù fadaka ati wura lọ. Ọlọrọ̀ ati talaka pejọ pọ̀: Oluwa li ẹlẹda gbogbo wọn. Ọlọgbọ́n enia ti ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́: ṣugbọn awọn òpe a kọja, a si jẹ wọn niya. Ere irẹlẹ ati ibẹ̀ru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati ìye. Ẹgún ati idẹkùn mbẹ li ọ̀na alayidayida: ẹniti o ba pa ọkàn rẹ̀ mọ́ yio jina si wọn. Tọ́ ọmọde li ọ̀na ti yio tọ̀: nigbati o si dàgba tan, kì yio kuro ninu rẹ̀. Ọlọrọ̀ ṣe olori olupọnju, ajigbese si ṣe iranṣẹ fun onigbese. Ẹniti o ba funrugbin ẹ̀ṣẹ, yio ri asan ka: ọpá ibinu rẹ̀ si ti mura tan. Ẹniti o li oju ãnu li a o bukun fun; nitoriti o fi ninu onjẹ rẹ̀ fun olupọnju. Ṣá ẹlẹgàn tì sode, ìja yio si jade; nitõtọ ìja ati ẹ̀gan yio dẹkun. Ẹniti o fẹ ìwa funfun aiya, ti o fẹ ọ̀rọ pẹlẹ, ọba yio ṣe ọrẹ́ rẹ̀. Oju Oluwa pa ìmọ mọ́, o si yi ọ̀rọ olurekọja po. Ọlẹ wipe, kiniun mbẹ lode, a o pa mi ni igboro. Ẹnu awọn ajeji obinrin, iho jijin ni; ẹniti a mbinu si lati ọdọ Oluwa wá ni yio ṣubu sinu rẹ̀. Li aiya ọmọde ni wère dì si; ṣugbọn paṣan itọ́ni ni yio le e jina kuro lọdọ rẹ̀. Ẹniti o nni talaka lara lati mu ọrọ̀ pọ̀, ti o si nta ọlọrọ̀ lọrẹ, yio di alaini bi o ti wu ki o ṣe. Dẹti rẹ silẹ, ki o gbọ́ ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si ẹkọ́ mi. Nitori ohun didùn ni bi iwọ ba pa wọn mọ́ ni inu rẹ; nigbati a si pese wọn tan li ète rẹ. Ki igbẹkẹle rẹ ki o le wà niti Oluwa, emi fi hàn ọ loni, ani fun ọ. Emi kò ti kọwe ohun daradara si ọ ni igbimọ ati li ẹkọ́, Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ? Máṣe ja talaka li ole, nitori ti iṣe talaka: bẹ̃ni ki o má si ṣe ni olupọnju lara ni ibode: Nitori Oluwa yio gbija wọn, yio si gbà ọkàn awọn ti ngbà lọwọ wọn. Máṣe ba onibinu enia ṣe ọrẹ́; má si ṣe ba ọkunrin oninu-fùfu rìn. Ki iwọ ki o má ba kọ́ ìwa rẹ̀, iwọ a si gbà ikẹkùn fun ara rẹ. Máṣe wà ninu awọn ti nṣe igbọwọ, tabi ninu awọn ti o duro fun gbèse. Bi iwọ kò ba ni nkan ti iwọ o fi san, nitori kini yio ṣe gbà ẹní rẹ kuro labẹ rẹ? Máṣe yẹ̀ àla ilẹ igbàni, ti awọn baba rẹ ti pa. Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.