Owe 20:1-15

Owe 20:1-15 YBCV

ẸLẸYA li ọti-waini, alariwo li ọti lile, ẹnikẹni ti a ba fi tanjẹ kò gbọ́n. Ibẹ̀ru ọba dabi igbe kiniun: ẹnikẹni ti o ba mu u binu, o ṣẹ̀ si ọkàn ara rẹ̀. Ọlá ni fun enia lati ṣiwọ kuro ninu ìja: ṣugbọn olukuluku aṣiwère ni ima ja ìja nla. Ọlẹ kò jẹ tu ilẹ nitori otutu; nitorina ni yio fi ma ṣagbe nigba ikore, kì yio si ni nkan. Ìmọ ninu ọkàn enia dabi omi jijin; ṣugbọn amoye enia ni ifà a jade. Ọ̀pọlọpọ enia ni ima fọnrere, olukuluku ọrẹ ara rẹ̀: ṣugbọn olõtọ enia tani yio ri i. Olõtọ enia nrìn ninu iwa-titọ rẹ̀: ibukún si ni fun awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀! Ọba ti o joko lori itẹ́ idajọ, o fi oju rẹ̀ fọ́n ìwa-ibi gbogbo ka. Tali o le wipe, Mo ti mu aiya mi mọ́, emi ti mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ mi? Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, bakanna ni mejeji ṣe irira loju Oluwa. Iṣe ọmọde pãpa li a fi imọ̀ ọ, bi ìwa rẹ̀ ṣe rere ati titọ. Eti igbọ́ ati oju irí, Oluwa li o ti dá awọn mejeji. Máṣe fẹ orun sisùn, ki iwọ ki o má ba di talaka; ṣi oju rẹ, a o si fi onjẹ tẹ ọ lọrùn. Kò ni lãri, kò ni lãri li oníbárà iwi; ṣugbọn nigbati o ba bọ si ọ̀na rẹ̀, nigbana ni iṣogo. Wura wà ati iyùn ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn ète ìmọ, èlo iyebiye ni.