Owe 12

12
1ẸNIKẸNI ti o fẹ ẹkọ́, o fẹ ìmọ: ṣugbọn ẹniti o korira ibawi, ẹranko ni.
2Enia rere ni ojurere lọdọ Oluwa: ṣugbọn enia ete buburu ni yio dalẹbi.
3A kì yio fi ẹsẹ enia mulẹ nipa ìwa-buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo kì yio fatu.
4Obinrin oniwa-rere li ade ọkọ rẹ̀: ṣugbọn eyi ti ndojuti ni dabi ọyún ninu egungun rẹ̀.
5Ìro olododo tọ́: ṣugbọn ìgbimọ awọn enia buburu, ẹ̀tan ni.
6Ọ̀rọ enia buburu ni lati luba fun ẹ̀jẹ: ṣugbọn ẹnu aduro-ṣinsin ni yio gbà wọn silẹ.
7A bì enia buburu ṣubu, nwọn kò si si: ṣugbọn ile olododo ni yio duro.
8A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn.
9Ẹniti a ngàn, ti o si ni ọmọ-ọdọ, o san jù ẹ̀niti nyìn ara rẹ̀ ti kò si ni onjẹ.
10Olododo enia mọ̀ ãjo ẹmi ẹran rẹ̀: ṣugbọn iyọ́nu awọn enia buburu, ìka ni.
11Ẹniti o ro ilẹ rẹ̀ li a o fi onjẹ tẹlọrun: ṣugbọn ẹniti ntọ̀ enia-lasan lẹhin ni oye kù fun.
12Enia buburu fẹ ilu-odi awọn enia buburu: ṣugbọn gbòngbo olododo so eso.
13Irekọja ète enia buburu li a fi idẹkùn rẹ̀: ṣugbọn olododo yio yọ kuro ninu ipọnju.
14Nipa ère ẹnu enia li a o fi ohun rere tẹ ẹ lọrun: ère-iṣẹ ọwọ enia li a o si san fun u.
15Ọ̀na aṣiwere tọ li oju ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o fetisi ìgbimọ li ọlọgbọ́n.
16Ibinu aṣiwere kò pẹ imọ̀: ṣugbọn amoye enia bò itiju mọlẹ.
17Ẹniti o sọ otitọ, o fi ododo hàn jade; ṣugbọn ẹlẹri eke, ẹ̀tan.
18Awọn kan mbẹ ti nyara sọ̀rọ lasan bi igunni idà; ṣugbọn ahọn ọlọgbọ́n, ilera ni.
19Ete otitọ li a o mu duro lailai; ṣugbọn ahọn eke, ìgba diẹ ni.
20Ẹtan wà li aiya awọn ti nrò ibi: ṣugbọn fun awọn ìgbimọ alafia, ayọ̀ ni.
21Kò si ibi kan ti yio ba olododo; ṣugbọn awọn enia buburu ni yio kún fun ibi.
22Irira loju Oluwa li ahọn eke; ṣugbọn awọn ti nṣe rere ni didùn-inu rẹ̀.
23Ọlọgbọ́n enia pa ìmọ mọ; ṣugbọn aiya awọn aṣiwere nkede iwere.
24Ọwọ alãpọn ni yio ṣe akoso; ṣugbọn ọlẹ ni yio wà labẹ irú-sisìn.
25Ibinujẹ li aiya enia ni idori rẹ̀ kọ odò; ṣugbọn ọ̀rọ rere ni imu u yọ̀.
26Olododo tọ́ aladugbo rẹ̀ si ọ̀na; ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu tàn wọn jẹ.
27Ọlẹ enia kò mu ohun ọdẹ rẹ̀; ṣugbọn lati jẹ alãpọn enia, ọrọ̀ iyebiye ni.
28Li ọ̀na olododo ni ìye; ikú kò si loju ọ̀na otitọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Owe 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀