Owe 11:1-31

Owe 11:1-31 YBCV

OṢUWỌN eke irira ni loju Oluwa; ṣugbọn òṣuwọn otitọ ni didùn inu rẹ̀. Bi igberaga ba de, nigbana ni itiju de, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu onirẹlẹ. Otitọ aduro-ṣinṣin ni yio ma tọ́ wọn; ṣugbọn arekereke awọn olurekọja ni yio pa wọn run. Ọrọ̀ kì ini anfani li ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ni igbani lọwọ ikú. Ododo ẹni-pipé yio ma tọ́ ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu ninu ìwa-buburu rẹ̀. Ododo awọn aduro-ṣinṣin yio gbà wọn là: ṣugbọn awọn olurekọja li a o mu ninu iṣekuṣe wọn: Nigbati enia buburu ba kú, ireti rẹ̀ a dasan, ireti awọn alaiṣedede enia a si dasan. A yọ olododo kuro ninu iyọnu, enia buburu a si bọ si ipò rẹ̀. Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ. Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta. Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu. Ẹniti oye kù fun gàn ọmọnikeji rẹ̀; ṣugbọn ẹni oye a pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Ẹniti nṣofofo fi ọ̀ran ipamọ́ hàn; ṣugbọn ẹniti nṣe olõtọ-ọkàn a pa ọ̀rọ na mọ́. Nibiti ìgbimọ kò si, awọn enia a ṣubu; ṣugbọn ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni ailewu. Ẹniti o ba ṣe onigbọwọ fun alejo, ni yio ri iyọnu; ẹniti o ba si korira iṣegbọwọ wà lailewu. Obinrin olore-ọfẹ gbà iyìn: bi alagbara enia ti igbà ọrọ̀. Alãnu enia ṣe rere fun ara rẹ̀: ṣugbọn ìka-enia nyọ ẹran-ara rẹ̀ li ẹnu. Enia buburu nṣiṣẹ ère-ẹ̀tan; ṣugbọn ẹniti ngbin ododo ni ère otitọ wà fun. Bi ẹniti o duro ninu ododo ti ini ìye, bẹ̃ni ẹniti nlepa ibi, o nle e si ikú ara rẹ̀. Awọn ti iṣe alarekereke aiya, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn inu rẹ̀ dùn si awọn aduroṣinṣin: Bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, enia buburu kì yio lọ laijiya, ṣugbọn iru-ọmọ olododo li a o gbàla. Bi oruka wura ni imu ẹlẹdẹ bẹ̃ni arẹwà obinrin ti kò moye. Kiki rere ni ifẹ inu awọn olododo; ṣugbọn ibinu ni ireti awọn enia buburu. Ẹnikan wà ti ntuka, sibẹ o mbi si i, ẹnikan si wà ti nhawọ jù bi o ti yẹ lọ, ṣugbọn kiki si aini ni. Ọkàn iṣore li a o mu sànra; ẹniti o mbomirin ni, ontikararẹ̀ li a o si bomirin pẹlu. Ẹniti o ba dawọ ọkà duro, on li enia o fibu: ṣugbọn ibukún yio wà li ori ẹniti o tà a. Ẹniti o fi ara balẹ wá rere, a ri oju-rere: ṣugbọn ẹniti o nwá ibi kiri, o mbọ̀wá ba a. Ẹniti o ba gbẹkẹle ọrọ̀ rẹ̀ yio ṣubu: ṣugbọn olododo yio ma gbà bi ẹka igi. Ẹniti o ba yọ ile ara rẹ̀ li ẹnu yio jogun ofo: aṣiwere ni yio ma ṣe iranṣẹ fun ọlọgbọ́n aiya. Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni. Kiye si i a o san a fun olododo li aiye: melomelo li enia buburu ati ẹ̀lẹṣẹ.