Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara; Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju: Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi; Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan. Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi. Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi, Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́
Kà Filp 3
Feti si Filp 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filp 3:3-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò