Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi: Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere: Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ. Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai; Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa. Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami. Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn.
Kà File 1
Feti si File 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: File 1:12-18
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò