Num 23
23
Àsọtẹ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ tí Balaamu Sọ
1BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin.
2Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi; ati Balaki ati Balaamu fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.
3Balaamu si wi fun Balaki pe, Duro tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ; bọya OLUWA yio wá pade mi: ohunkohun ti o si fihàn mi emi o wi fun ọ. O si lọ si ibi giga kan.
4Ọlọrun si pade Balaamu: o si wi fun u pe, Emi ti pèse pẹpẹ meje silẹ, mo si ti fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.
5OLUWA si fi ọ̀rọ si Balaamu li ẹnu, o si wipe, Pada tọ̀ Balaki lọ, bayi ni ki iwọ ki o si sọ.
6O si pada tọ̀ ọ lọ, si kiyesi i, on duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, on ati gbogbo awọn ijoye Moabu.
7O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.
8Emi o ti ṣe fibú, ẹniti Ọlọrun kò fibú? tabi emi o si ti ṣe firé, ẹniti OLUWA kò firé?
9Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède.
10Tali o le kà erupẹ Jakobu, ati iye idamẹrin Israeli? Jẹ ki emi ki o kú ikú olododo, ki igbẹhin mi ki o si dabi tirẹ̀!
11Balaki si wi fun Balaamu pe, Kini iwọ nṣe si mi yi? mo mú ọ wá lati fi awọn ọtá mi bú, si kiyesi i, iwọ si sure fun wọn patapata.
12On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?
Àsọtẹ́lẹ̀ Keji tí Balaamu Sọ
13Balaki si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, bá mi lọ si ibomiran, lati ibiti iwọ o le ri wọn; kìki apakan wọn ni iwọ o ri, iwọ ki yio si ri gbogbo wọn tán; ki o si fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
14O si mú u wá si igbẹ Sofimu sori òke Pisga, o si mọ pẹpẹ meje, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.
15On si wi fun Balaki pe, Duro nihin tì ẹbọ sisun rẹ, emi o si lọ ipade OLUWA lọhùn yi.
16OLUWA si pade Balaamu, o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu, wipe, Tun pada tọ̀ Balaki lọ, ki o si wi bayi.
17O si tọ̀ ọ wá, kiyesi i, o duro tì ẹbọ sisun rẹ̀, ati awọn ijoye Moabu pẹlu rẹ̀. Balaki si bi i pe, Kini OLUWA sọ?
18O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Dide, Balaki, ki o si gbọ́; ki o si fetisi mi, iwọ ọmọ Sipporu:
19Ọlọrun ki iṣe enia ti yio fi ṣeké; bẹ̃ni ki iṣe ọmọ enia ti yio fi ronupiwada: a ma wi, ki o má si ṣe bi? tabi a ma sọ̀rọ ki o má mu u ṣẹ?
20Kiyesi i, emi gbà aṣẹ ati sure: on si ti sure, emi kò si le yì i.
21On kò ri ẹ̀ṣẹ ninu Jakobu, bẹ̃ni kò ri ibi ninu Israeli: OLUWA Ọlọrun rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ihó-ayọ ọba si mbẹ ninu wọn.
22Ọlọrun mú wọn lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere.
23Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe!
24Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa.
25Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára.
26Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?
Àsọtẹ́lẹ̀ Kẹta Tí Balaamu Sọ
27Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
28Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù.
29Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin.
30Balaki si ṣe bi Balaamu ti wi, o si fi akọmalu kan ati àgbo kan rubọ lori pẹpẹ kọkan.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.