Num 19

19
Eérú Mààlúù Pupa náà
1OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́:
3Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀:
4Ki Eleasari alufa, ki o fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n iwaju agọ́ ajọ ni ìgba meje.
5Ki ẹnikan ki o si sun ẹgbọrọ abomalu na li oju rẹ̀; awọ rẹ̀, ati ẹran rẹ̀, ati ẹ̀jẹ rẹ̀, pẹlu igbẹ́ rẹ̀, ni ki o sun:
6Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun.
7Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
8Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
9Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
10Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.
Òfin Tí ó Jẹ Mọ́ Fífi Ara Kan òkú
11Ẹniti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ki o jẹ́ alaimọ ni ijọ́ meje.
12Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́.
13Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀,
14Eyi li ofin na, nigbati enia kan ba kú ninu agọ́ kan: gbogbo ẹniti o wọ̀ inu agọ́ na, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu agọ́ na, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.
15Ati ohun-èlo gbogbo ti o ṣi silẹ, ti kò ní ideri lori rẹ̀, alaimọ́ ni.
16Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.
17Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan:
18Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú:
19Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ.
20Ṣugbọn ẹniti o ba jẹ́ alaimọ́, ti kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, ọkàn na li a o ke kuro ninu ijọ, nitoriti o bà ibi-mimọ́ OLUWA jẹ́: a kò si ta omi ìyasapakan si i lara; alaimọ́ li on.
21Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
22Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 19: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀