Njẹ nitorina, Ọlọrun wa, Ọlọrun ti o tobi, ti o li agbara, ti o si li ẹ̀ru, ẹniti npa majẹmu ati ãnu mọ, má jẹ ki gbogbo iyọnu na dabi ohun kekere niwaju rẹ, o de bá wa, awọn ọba wa, awọn ijoye wa, ati awọn alufa wa, ati awọn woli wa, ati awọn baba wa, ati gbogbo awọn enia rẹ lati akoko ọba Assiria wá, titi o fi di oni yi.
Sibẹ, iwọ ṣe olododo ninu ohun gbogbo ti o de ba wa, iwọ si ti ṣe otitọ, ṣugbọn awa ti ṣe buburu:
Awọn ọba wa, awọn ijoye wa, awọn alufa wa, ati awọn baba wa, kò pa ofin rẹ mọ, bẹ̃ni nwọn kò fi eti si aṣẹ rẹ, ati ẹri rẹ, ti iwọ fi jẹri gbè wọn.
Nitori ti nwọn kò sin ọ ninu ijọba wọn, ati ninu ore rẹ nla ti iwọ fi fun wọn, ati ninu ilẹ nla ati ọlọra ti o fi si iwaju wọn, bẹ̃ni nwọn kò pada kuro ninu iṣẹ buburu wọn.
Kiyesi i, ẹrú li awa iṣe li oni yi, ati ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa lati ma jẹ eso rẹ̀, ati ire rẹ̀, kiyesi i, awa jẹ ẹrú ninu rẹ̀.
Ilẹ na si mu ohun ọ̀pọlọpọ wá fun awọn ọba, ti iwọ ti fi ṣe olori wa nitori ẹ̀ṣẹ wa: nwọn ni aṣẹ lori ara wa pẹlu, ati lori ẹran-nla wa, bi o ti wù wọn, awa si wà ninu wàhala nla.