Esra si ṣi iwe na li oju gbogbo enia; (nitori on ga jù gbogbo enia) nigbati o si ṣi i, gbogbo enia dide duro:
Esra si fi ibukun fun Oluwa Ọlọrun, ti o tobi. Gbogbo enia si dahun pe, Amin, Amin! pẹlu gbigbe ọwọ wọn soke: nwọn si tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn Oluwa ni idojubòlẹ̀.
Jeṣua pẹlu ati Bani, ati Ṣerebiah, Jamini, Akkubu, Ṣabbetai, Hodijah, Maaseiah, Kelita, Asariah, Josabadi, Hanani, Pelaiah, ati awọn ọmọ Lefi, mu ki ofin ye awọn enia: awọn enia si duro ni ipò wọn.
Bẹ̃ni nwọn kà ninu iwe ofin Ọlọrun ketekete, nwọn tumọ rẹ̀, nwọn si mu ki iwe kikà na ye wọn.
Ati Nehemiah ti iṣe bãlẹ, ati Esra alufa, akọwe, ati awọn ọmọ Lefi, ti o kọ́ awọn enia wi fun gbogbo enia pe, Ọjọ yi jẹ mimọ́ fun Oluwa Ọlọrun nyin; ẹ má ṣọ̀fọ ki ẹ má si sọkún. Nitori gbogbo awọn enia sọkún, nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ ofin.
Nigbana ni o wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ jẹ ọ̀ra ki ẹ si mu ohun didùn, ki ẹ si fi apakan ipin ranṣẹ si awọn ti a kò pèse fun: nitori mimọ́ ni ọjọ yi fun Oluwa: ẹ máṣe banujẹ; nitori ayọ̀ Oluwa on li agbàra nyin.