Neh 5
5
Níni Àwọn Talaka Lára
1AWỌN enia ati awọn aya wọn si nkigbe nlanla si awọn ara Juda, arakunrin wọn.
2Nitori awọn kan wà ti nwọn wipe, Awa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, jẹ pipọ: nitorina awa gba ọkà, awa si jẹ, a si yè.
3Awọn ẹlomiran wà pẹlu ti nwọn wipe, Awa ti fi oko wa, ọgba-ajara wa, ati ile wa, sọfa, ki awa ki o le rà ọkà ni ìgba ìyan.
4Ẹlomiran si wipe, Awa ti ṣi owo lati san owo-ori ọba li ori oko wa, ati ọgba-ajara wa.
5Ati sibẹ ẹran-ara wa si dabi ẹran-ara awọn arakunrin wa, ọmọ wa bi ọmọ wọn: si wo o, awa mu awọn arakunrin wa ati awọn arabinrin wa wá si oko-ẹrú, lati jẹ iranṣẹ, a si ti mu ninu awọn ọmọbinrin wa wá si oko-ẹrú na: awa kò ni agbara lati rà wọn padà: nitori awọn ẹlomiran li o ni oko wa ati ọgbà ajara wa.
6Emi si binu gidigidi nigbati mo gbọ́ igbe wọn ati ọ̀rọ wọnyi.
7Mo si ronu ọ̀ran na, mo si ba awọn ijoye ati awọn olori wi, mo si wi fun wọn pe, Ẹnyin ngba ẹdá olukuluku lọwọ arakunrin rẹ̀. Mo si pe apejọ nla tì wọn.
8Mo si wi fun wọn pe, Awa nipa agbara wa ti rà awọn ara Juda arakunrin wa padà, ti a tà fun awọn keferi; ẹnyin o ha si mu ki a tà awọn arakunrin nyin? tabi ki a ha tà wọn fun wa? Nwọn si dakẹ, nwọn kò ri nkankan dahùn.
9Mo si wi pẹlu pe, Ohun ti ẹ ṣe kò dara: kò ha yẹ ki ẹ ma rìn ninu ìbẹru Ọlọrun wa, nitori ẹgan awọn keferi ọta wa?
10Emi pẹlu, ati awọn arakunrin mi, ati awọn ọmọkunrin mi, nyá wọn ni owó ati ọkà, ẹ jẹ ki a pa èlé gbígbà yí tì.
11Mo bẹ̀ nyin, ẹ fi oko wọn, ọgbà-ajarà wọn, ọgbà-olifi wọn, ati ile wọn, ida-ọgọrun owo na pẹlu, ati ti ọkà, ọti-waini, ati ororo wọn, ti ẹ fi agbara gbà, fun wọn padà loni yi.
12Nwọn si wipe, Awa o fi fun wọn pada, awa kì yio si bere nkankan lọwọ wọn; bẹ̃li awa o ṣe bi iwọ ti wi. Nigbana ni mo pe awọn alufa, mo si mu wọn bura pe, nwọn o ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
13Mo si gbọ̀n apo aṣọ mi, mo si wipe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o gbọ̀n olukuluku enia kuro ni ile rẹ̀, ati kuro ninu iṣẹ rẹ̀, ti kò mu ileri yi ṣẹ, ani bayi ni ki a gbọ̀n ọ kuro, ki o si di ofo. Gbogbo ijọ si wipe, Amin! nwọn si fi iyìn fun Oluwa. Awọn enia na si ṣe gẹgẹ bi ileri yi.
Àìní Ìwà Ìmọ-Tara-Ẹni Nìkan Nehemiah
14Pẹlupẹlu lati akoko ti a ti yàn mi lati jẹ bãlẹ wọn ni ilẹ Juda, lati ogún ọdun titi de ọdun kejilelọgbọn Artasasta ọba, eyinì ni, ọdun mejila, emi ati awọn arakunrin mi kò jẹ onjẹ bãlẹ.
15Ṣugbọn awọn bãlẹ iṣaju, ti o ti wà, ṣaju mi, di ẹrù wiwo le lori awọn enia, nwọn si ti gbà akara ati ọti-waini, laika ogoji ṣekeli fadaka; pẹlupẹlu awọn ọmọkunrin wọn tilẹ lo agbara lori enia na: ṣugbọn emi kò ṣe bẹ̃ nitori ibẹ̀ru Ọlọrun.
16Mo si mba iṣẹ odi yi lọ pẹlu, awa kò si rà oko kan: gbogbo awọn ọmọkunrin mi li o si gbajọ sibẹ si iṣẹ na.
17Pẹlupẹlu awọn ti o joko ni tabili mi jẹ ãdọjọ enia ninu awọn ara Juda ati ninu awọn ijoye, laika awọn ti o wá sọdọ wa lati ãrin awọn keferi ti o wà yi wa ka.
18Njẹ ẹran ti a pese fun mi jẹ malũ kan ati ãyo agutan mẹfa; fun ijọ kan ni a pese adiẹ fun mi pẹlu, ati lẹ̃kan ni ijọ mẹwa onirũru ọti-waini: ṣugbọn fun gbogbo eyi emi kò bere onjẹ bãlẹ, nitori iṣẹ na wiwo lori awọn enia yi.
19Ranti mi, Ọlọrun mi, fun rere, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti mo ti ṣe fun enia yi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Neh 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.