Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi. Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀. Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀. O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ. Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀. Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.
Kà Nah 1
Feti si Nah 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Nah 1:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò