Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu.
O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? O si wipe, Lati kekere ni.
Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ.
Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́.
Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ.
Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́.
On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú.
Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide.
Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade?
O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ.