Mak 9:1-29

Mak 9:1-29 YBCV

O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara. Lẹhin ijọ mẹfa Jesu si mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu, o si mu wọn lọ sori òke giga li apakan awọn nikan: ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn. Aṣọ rẹ̀ si di didán, o si funfun gidigidi; afọṣọ kan li aiye kò le fọ̀ aṣọ fún bi iru rẹ̀. Elijah pẹlu Mose si farahàn fun wọn: nwọn si mba Jesu sọ̀rọ. Peteru si dahùn o si wi fun Jesu pe, Olukọni, o dara fun wa lati ma gbé ihinyi: si jẹ ki a pa agọ́ mẹta, ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah. On kò sá mọ̀ eyi ti iba wi; nitori ẹ̀ru bà wọn gidigidi. Ikuku kan si wá, o ṣiji bò wọn; ohùn kan si ti inu ikuku na wá, o ni, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi: ẹ mã gbọ́ tirẹ̀. Lojiji, nigbati nwọn si wò yika, nwọn ko si ri ẹnikan mọ́, bikoṣe Jesu nikan pẹlu ara wọn. Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, o paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun ti nwọn ri fun ẹnikan, bikoṣe igbati Ọmọ-enia ba ti jinde kuro ninu okú. Nwọn si fi ọ̀rọ na pamọ́ sinu ara wọn, nwọn si mbi ara wọn lẽre, kili ajinde kuro ninu okú iba jẹ. Nwọn si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Elijah ni yio tètekọ de? O si dahùn o si wi fun wọn pe, Lõtọ, ni Elijah yio tètekọ, de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò; ati gẹgẹ bi a ti kọwe rẹ̀ nipa ti Ọmọ-enia pe, ko le ṣaima jìya ohun pipọ, ati pe a o si kọ̀ ọ silẹ. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn si ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i, gẹgẹ bi a ti kọwe nipa rẹ̀. Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran. Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i. O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn? Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá; Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e. O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi. Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu. O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? O si wipe, Lati kekere ni. Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ. Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́. Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ. Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́. On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú. Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide. Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade? O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ.