O si wi fun wọn pe, A ha gbé fitilà wá lati fi sabẹ òṣuwọn, tabi sabẹ akete, ki a ma si ṣe gbé e kà ori ọpá fitilà? Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba. Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. O si wi fun wọn pe, Ẹ mã kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ́: òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o fi wọ̀n fun nyin: a o si fi kún u fun nyin. Nitori ẹniti o ba ni, on li a o fifun: ati ẹniti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.
Kà Mak 4
Feti si Mak 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 4:21-25
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò