O si gùn ori òke lọ, o si npè ẹnikẹni ti o fẹ sọdọ rẹ̀: nwọn si tọ̀ ọ wá. O si yàn awọn mejila, ki nwọn ki o le mã gbé ọdọ rẹ̀, ati ki o le ma rán wọn lọ lati wasu, Ati lati li agbara lati wò arunkarun san, ati lati lé awọn ẹmi èṣu jade: Simoni ẹniti o si sọ apele rẹ̀ ni Peteru; Ati Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin Jakọbu; o si sọ apele wọn ni Boanerge, eyi ti ijẹ Awọn ọmọ ãrá: Ati Anderu, ati Filippi, ati Bartolomeu, ati Matiu, ati Tomasi, ati Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Taddeu, ati Simoni ti a npè ni Selote, Ati Judasi Iskariotu, ẹniti o si fi i hàn pẹlu: nwọn si wọ̀ ile kan lọ.
Kà Mak 3
Feti si Mak 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 3:13-19
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò