Mak 3:1-12

Mak 3:1-12 YBCV

O si tún wọ̀ inu sinagogu lọ; ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le fi i sùn. O si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, duro larin. O si wi fun wọn pe, O tọ́ lati mã ṣe rere li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run? Nwọn si dakẹ. Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji. Awọn Farisi jade lọ lojukanna lati ba awọn ọmọ-ẹhin Herodu gbìmọ pọ̀ si i, bi awọn iba ti ṣe pa a. Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si kuro nibẹ̀ lọ si eti okun: ijọ enia pipọ lati Galili ati Judea wá si tọ̀ ọ lẹhin, Ati lati Jerusalemu, ati lati Idumea, ati lati oke odò Jordani, ati awọn ti o wà niha Tire on Sidoni, ijọ enia pipọ; nigbati nwọn gbọ́ ohun nla ti o ṣe, nwọn tọ̀ ọ wá. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn mu ọkọ̀ kekere kan sunmọ on, nitori ijọ enia, ki nwọn ki o má bà bilù u. Nitoriti o mu ọ̀pọ enia larada; tobẹ̃ ti nwọn mbì ara wọn lù u lati fi ọwọ́ kàn a, iye awọn ti o li arùn. Ati awọn ẹmi aimọ́, nigbàkugba ti nwọn ba ri i, nwọn a wolẹ niwaju rẹ̀, nwọn a kigbe soke, wipe, Iwọ li Ọmọ Ọlọrun. O si kìlọ fun wọn gidigidi pe, ki nwọn ki o máṣe fi on hàn.