Nigbati nwọn si wọ̀ inu ibojì na, nwọn ri ọmọkunrin kan joko li apa ọtún, ti o wọ̀ agbada funfun; ẹ̀ru si ba wọn. O si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin nwá Jesu ti Nasareti, ti a kàn mọ agbelebu: o jinde; kò si nihinyi: ẹ wò ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si. Ṣugbọn ẹ lọ, ki ẹ si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati Peteru pe, o ṣaju nyin lọ si Galili: nibẹ̀ li ẹnyin ó gbe ri i, bi o ti wi fun nyin.
Kà Mak 16
Feti si Mak 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 16:5-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò