Li ọjọ kini ajọ aiwukara, nigbati nwọn npa ẹran irekọja, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo ni iwọ nfẹ ki a lọ ipèse silẹ, ki iwọ́ ki o le jẹ irekọja. O si rán awọn meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si ilu, ọkunrin kan ti nrù ìṣa omi yio pade nyin: ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin. Ati ibikibi ti o ba gbé wọ̀, ki ẹnyin ki o wi fun bãle na pe, Olukọni wipe, Nibo ni gbọ̀ngan apejẹ na gbé wà, nibiti emi o gbé jẹ irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi? On o si fi gbọ̀ngan nla kan loke hàn nyin, ti a ṣe lọṣọ, ti a si pèse tẹlẹ; nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o pèse silẹ dè wa. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si jade lọ, nwọn wá si ilu, nwọn si ri i gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: nwọn si pèse irekọja silẹ.
Kà Mak 14
Feti si Mak 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 14:12-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò