Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.
Kà Mak 13
Feti si Mak 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 13:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò