Mak 10:35-45

Mak 10:35-45 YBCV

Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa. O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin? Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère: ẹnyin le mu ago ti emi mu? tabi ki a fi baptismu ti a fi baptisi mi baptisi nyin? Nwọn si wi fun u pe, Awa le ṣe e. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin ó mu ago ti emi mu; ati baptismu ti a o fi baptisi mi li a o fi baptisi nyin: Ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún mi ati li ọwọ́ òsi mi ki iṣe ti emi lati fi funni: bikoṣe fun awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ. Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́, nwọn bẹ̀re si ibinu si Jakọbu ati Johanu. Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba. Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ tobi lãrin nyin, on ni yio ṣe iranṣẹ nyin: Ati ẹnikẹni ninu nyin ti o ba fẹ ṣe olori, on ni yio ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo nyin. Nitori Ọmọ-enia tikalarẹ̀ kò ti wá ki a ba mã ṣe iranṣẹ fun, bikoṣe lati mã ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada fun ọ̀pọlọpọ enia.