Mak 10:17-30

Mak 10:17-30 YBCV

Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun? Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? Ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun. Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ. O si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo nkan wọnyi li emi ti nkiyesi lati igba ewe mi wá. Nigbana ni Jesu sì wò o, o fẹràn rẹ̀, o si wi fun u pe, Ohun kan li o kù ọ kù: lọ tà ohunkohun ti o ni ki o si fifun awọn talakà, iwọ ó si ni iṣura li ọrun: si wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Inu rẹ̀ si bajẹ si ọ̀rọ̀ na, o si jade lọ ni ibinujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pipọ. Jesu si wò yiká, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! Ẹnu si yà awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu si tun dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ, yio ti ṣoro to fun awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun! O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ. Ẹnu si yà wọn rekọja, nwọn si mba ara wọn sọ wipe, Njẹ tali o ha le là? Jesu si wò wọn o wipe, Enia li eyi ko le ṣe iṣe fun, ṣugbọn ki iṣe fun Ọlọrun: nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun. Nigbana ni Peteru bẹ̀rẹ si iwi fun u pe, Wo o, awa ti fi gbogbo nkan silẹ awa si ti tọ̀ ọ lẹhin. Jesu si dahùn, o wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere, Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mak 10:17-30