Mik 7:1-20

Mik 7:1-20 YBCV

EGBE ni fun mi! nitori emi dàbi ikojọpọ̀ eso ẹ̃rùn, bi ẽṣẹ́ ikorè eso àjara: kò si ití kan lati jẹ: akọso ti ọkàn mi fẹ. Oninurere ti run kuro li aiye: kò si si olotitọ kan ninu enia: gbogbo wọn ba fun ẹ̀jẹ, olukuluku wọn nfi àwọn dẹ arakunrin rẹ̀. Ọwọ́ wọn ti mura tan lati ṣe buburu, olori mbère, onidajọ si mbère fun ẹsan; ẹni-nla nsọ ìro ika rẹ̀, nwọn si nyi i po. Ẹniti o sànjulọ ninu wọn dàbi ẹ̀gun: ìduroṣiṣin julọ mú jù ẹgún ọgbà lọ: ọjọ awọn olùṣọ rẹ ati ti ìbẹwo rẹ de; nisisiyi ni idãmu wọn o de. Ẹ má gba ọrẹ́ kan gbọ́, ẹ má si gbẹkẹ̀le amọ̀na kan: pa ilẹkùn ẹnu rẹ mọ fun ẹniti o sùn ni õkan-àiya rẹ. Nitori ọmọkunrin nṣàibọ̀wọ fun baba, ọmọbinrin dide si ìya rẹ̀, aya-ọmọ si iyakọ rẹ̀; ọta olukuluku ni awọn ara ile rẹ̀. Nitorina emi o ni ireti si Oluwa: emi o duro de Ọlọrun igbala mi: Ọlọrun mi yio gbọ́ temi. Má yọ̀ mi, Iwọ ọta mi: nigbati mo ba ṣubu, emi o dide; nigbati mo ba joko li okùnkun, Oluwa yio jẹ imọlẹ fun mi. Emi o rù ibinu Oluwa, nitori emi ti dẹṣẹ si i, titi yio fi gbà ẹjọ mi rò, ti yio si ṣe idajọ mi; yio mu mi wá si imọlẹ, emi o si ri ododo rẹ̀. Nitori ọta mi yio ri i, itiju yio si bò ẹniti o wipe, Nibo ni Oluwa Ọlọrun rẹ wà? oju mi yio ri i, nisisiyi ni yio di itẹ̀mọlẹ bi ẹrẹ̀ ita. Ọjọ ti a o mọ odi rẹ, ọjọ na ni aṣẹ yio jinà rére. Ọjọ na ni nwọn o si ti Assiria wá sọdọ rẹ, ati lati ilu olodi, ati lati ile iṣọ́ alagbara titi de odò, ati lati okun de okun, ati oke-nla de oke-nla. Ilẹ na yio si di ahoro fun awọn ti ngbe inu rẹ̀, nitori eso ìwa wọn. Fi ọpa rẹ bọ́ enia agbo ini rẹ, ti ndágbe inu igbó lãrin Karmeli: jẹ ki wọn jẹ̀ ni Baṣani ati Gileadi, bi ọjọ igbãni. Bi ọjọ ti o jade kuro ni ilẹ Egipti li emi o fi ohun iyanu han a. Awọn orilẹ-ède yio ri, oju o si tì wọn ninu gbogbo agbara wọn: nwọn o fi ọwọ́ le ẹnu, eti wọn o si di. Nwọn o lá erùpẹ bi ejò, nwọn o si jade kuro ninu ihò wọn bi ekòlo ilẹ: nwọn o bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa, nwọn o si bẹ̀ru nitori rẹ. Tani Ọlọrun bi iwọ, ti o ndari aiṣedede jì, ti o nre iyokù ini rẹ̀ kọja? kò dá ibinu rẹ̀ duro titi lai, nitori on ni inudidun si ãnu. Yio yipadà, yio ni iyọnú si wa; yio si tẹ̀ aiṣedede wa ba; iwọ o si sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ wọn sinu ọgbun okun. Iwọ o fi otitọ fun Jakobu, ãnu fun Abrahamu, ti iwọ ti bura fun awọn baba wa, lati ọjọ igbani.