Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye. Nitorina ni yio ṣe jọwọ wọn lọwọ, titi di akokò ti ẹniti nrọbi yio fi bi: iyokù awọn arakunrin rẹ̀ yio si pada wá sọdọ awọn ọmọ Israeli. On o si duro yio si ma jẹ̀ li agbara Oluwa, ni ọlanla orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀; nwọn o si wà, nitori nisisiyi ni on o tobi titi de opin aiye.
Kà Mik 5
Feti si Mik 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mik 5:2-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò