O si bọ sinu ọkọ̀, o rekọja, o si wá si ilu on tikararẹ̀.
Si kiyesi i, nwọn gbé ọkunrin kan ti o li ẹ̀gba wá sọdọ rẹ̀, o dubulẹ lori akete; nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọkunrin, tújuka, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.
Si kiyesi i, awọn ọkan ninu awọn akọwe nwi ninu ara wọn pe, ọkunrin yi nsọrọ-odi.
Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?
Ewo li o rọrun ju, lati wipe, A dari ẹṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, ki o si mã rìn?
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o si wi fun alarun ẹ̀gba na pe,) Dide, si gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.
O si dide, o si lọ ile rẹ̀.
Nigbati ijọ enia si rí i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.
Bi Jesu si ti nrekọja lati ibẹ̀ lọ, o ri ọkunrin kan ti a npè ni Matiu joko ni bode; o sì wi fun u pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. O si dide, o tọ̀ ọ lẹhin.
O si ṣe, bi Jesu ti joko tì onjẹ ninu ile, si kiyesi i, ọ̀pọ awọn agbowode ati ẹlẹṣẹ wá, nwọn si ba a joko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Nigbati awọn Farisi si ri i, nwọn wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Olukọ nyin fi mba awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ jẹun pọ̀?
Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.
Ṣugbọn ẹ lọ ẹ si kọ́ bi ã ti mọ̀ eyi si, Anu li emi nfẹ, kì iṣe ẹbọ: nitori emi kò wá lati pè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Johanu tọ̀ ọ wá wipe, Èṣe ti awa ati awọn Farisi fi ngbàwẹ nigbagbogbo, ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko gbàwẹ?
Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.
Ko si ẹniti ifi idãsa aṣọ titun lẹ ogbologbó ẹ̀wu; nitori eyi ti a fi lẹ ẹ o mu kuro li oju ẹ̀lẹ, aṣọ na a si mã ya siwaju.
Bẹ̃ni ko si ẹniti ifi waini titun sinu ogbologbo igo-awọ; bi a ba ṣe bẹ̃, igo-awọ yio bẹ́, waini a si tú jade, igo-awọ a si ṣegbe; ṣugbọn waini titun ni nwọn ifi sinu igo-awọ titun, awọn mejeji a si ṣe dede.
Bi o ti nsọ nkan wọnyi fun wọn, kiyesi i, ijoye kan tọ̀ ọ wá, o si tẹriba fun u, wipe, Ọmọbinrin mi kú nisisiyi, ṣugbọn wá fi ọwọ́ rẹ le e, on ó si yè.
Jesu dide, o si ba a lọ, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.