Ati pẹlu nigbati ẹnyin ba ngbàwẹ, ẹ máṣe dabi awọn agabagebe ti nfajuro; nwọn a ba oju jẹ, nitori ki nwọn ki o ba le farahàn fun enia pe nwọn ngbàwẹ. Lõtọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gbà ère wọn na.
Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;
Ki iwọ ki o máṣe farahàn fun enia pe iwọ ngbàwẹ, bikoṣe fun Baba rẹ ti o mbẹ ni ìkọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ìkọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.
Ẹ máṣe tò iṣura jọ fun ara nyin li aiye, nibiti kòkoro ati ipãra ibà a jẹ, ati nibiti awọn olè irunlẹ ti nwọn si ijale:
Ṣugbọn ẹ tò iṣura jọ fun ara nyin li ọrun, nibiti kòkoro ati ipãra ko le bà a jẹ, ati nibiti awọn olè kò le runlẹ ki nwọn si jale.
Nitori nibiti iṣura nyin bá gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu.
Oju ni fitila ara: nitorina bi oju rẹ ba mọ́, gbogbo ara rẹ ni yio kún fun imọlẹ.
Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!
Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mamoni.
Nitorina mo wi fun nyin, Ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ẹmí nyin ohun ti ẹ ó jẹ, ati fun ara nyin ohun ti ẹ o fi bora. Ẹmí kò ha jù onjẹ lọ? tabi ara ni kò jù aṣọ lọ?
Ẹ sá wò ẹiyẹ oju ọrun; nwọn kì ifunrugbin, bẹ̃ni nwọn kì ikore, nwọn kì isi ikójọ sinu abà, ṣugbọn Baba nyin ti mbẹ li ọrun mbọ́ wọn. Ẹnyin kò ha san jù wọn lọ?
Tani ninu nyin nipa aniyàn ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀?
Ẽṣe ti ẹnyin sì fi nṣe aniyan nitori aṣọ? Kiyesi lili ti mbẹ ni igbẹ́, bi nwọn ti ndàgba; nwọn kì iṣiṣẹ, bẹ̃ni nwọn kì irànwu:
Mo si wi fun nyin pe, a ko ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ̀ to bi ọkan ninu wọnyi.
Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ bẹ̃, eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu iná lọla, melomelo ni ki yio fi le wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin oni-kekere igbagbọ?
Nitorina ẹ maṣe ṣe aniyan, wipe, Kili a o jẹ? tabi, Kili a o mu? tabi, aṣọ wo li a o fi wọ̀ wa?
Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi.
Ṣugbọn ẹ tète mã wá ijọba Ọlọrun na, ati ododo rẹ̀; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún u fun nyin.
Nitorina ẹ máṣe ṣe aniyan nitori ọla; ọla ni yio ṣe aniyan ohun ara rẹ̀. Buburu ti õjọ to fun u.