Mat 27:27-56

Mat 27:27-56 YBCV

Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu. Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Golgota, eyini ni, Ibi agbari, Nwọn fi ọti kikan ti a dàpọ mọ orõrò fun u lati mu: nigbati o si tọ́ ọ wò, o kọ̀ lati mu u. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le. Nwọn si joko, nwọn nṣọ ọ nibẹ̀. Nwọn si fi ọ̀ran ifisùn rẹ̀ ti a kọ si igberi rẹ̀, EYI NI JESU ỌBA AWỌN JU. Nigbana li a kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi. Awọn ti nkọja lọ si nfi ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu awọn akọwe, ati awọn àgbãgba nfi ṣe ẹlẹya, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́. O gbẹkẹle Ọlọrun; jẹ ki o gbà a là nisisiyi, bi o ba fẹran rẹ̀: o sá wipe, Ọmọ Ọlọrun li emi. Awọn olè ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nfi eyi na gún u loju bakanna. Lati wakati kẹfa, ni òkunkun ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Niwọn wakati kẹsan ni Jesu si kigbe li ohùn rara wipe, Eli, Eli, lama sabaktani? eyini ni, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọkunrin yi npè Elijah. Lojukanna ọkan ninu wọn si sare, o mu kànìnkànìn, o tẹ̀ ẹ bọ̀ inu ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o si fifun u mu. Awọn iyokù wipe, Ẹ fi silẹ̀, ẹ jẹ ki a mã wò bi Elijah yio wá gbà a là. Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 27:27-56