Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.
Kà Mat 26
Feti si Mat 26
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 26:36-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò