Nitori ijọba ọrun dabi ọkunrin kan ti o nlọ si àjo, ẹniti o pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, o si kó ẹrù rẹ̀ fun wọn.
O si fi talenti marun fun ọkan, o fi meji fun ẹnikeji, ati ọkan fun ẹnikẹta; o fifun olukuluku gẹgẹ bi agbara rẹ̀ ti ri; lẹsẹkanna o mu ọ̀na àjo rẹ̀ pọ̀n.
Nigbana li eyi ti o gbà talenti marun lọ, ọ fi tirẹ̀ ṣòwo, o si jère talenti marun miran.
Gẹgẹ bẹ̃li eyi ti o gbà meji, on pẹlu si jère meji miran.
Ṣugbọn eyi ti o gbà talenti kan lọ, o wà ilẹ, o si rì owo oluwa rẹ̀.
Lẹhin igba ti o pẹ titi, oluwa awọn ọmọ-ọdọ wọnni de, o ba wọn ṣiro.
Eyi ti o gbà talenti marun si wá, o si mu talenti marun miran wá pẹlu, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti marun fun mi: si wò o, mo jère talenti marun miran.
Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ.
Eyi ti o gbà talenti meji pẹlu si wá, o wipe, Oluwa, iwọ fi talenti meji fun mi: wo o, mo jère talenti meji miran.
Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.